Africa | Nigeria
Responsive image

Abortion Laws in Nigeria

Responsive image

Is abortion legal in Nigeria?

Abortion is only permitted in Nigeria to save the life of a woman. Two separate abortion laws govern the Northern and Southern regions of Nigeria, with the Southern region allowing abortions to preserve both the physical and mental wellbeing of the woman. The Northern region is majority Muslim and is governed by the Penal Code while the Southern region is majority Christian and governed by the Criminal Code.

In 1982, the Nigerian Society of Gynecologists and Obstetricians supported a termination of pregnancy bill that sought to expand the circumstances under which and abortion should be allowed. The bill would have allowed an abortion if the continuation of the pregnancy posed a great risk to the wellbeing of the woman’s existing children and if there was a substantial risk of the child being born with mental abnormalities and/or physical handicaps. The bill was strongly opposed by religious leaders and the Nigerian National Council of Women’s Societies who believed the passage of the bill would increase promiscuity within society. The abortion law remains unchanged to date.

Responsive image

What are the different Post Abortion Care (PAC) services available in Nigeria?

 • Medical methods: Using pills such as misoprostol (Cytotec, Miso Fem, Vanprazol-200 )
 • Surgical methods: Manual Vacuum Aspiration (MVA)
Responsive image

Who can perform legal abortions and PAC in Nigeria?

Only licensed and trained health practitioners at certified government and/or private health centers can legally induce abortions (under certain circumstances) and provide PAC.

Note: The law allows health care providers to refuse to terminate a pregnancy on religious, moral and ethical grounds.

Responsive image

Where can I go for safe legal abortions and PAC services in Nigeria?

Legal abortions and PAC services can only be performed by trained and licensed health care providers and should be accessible at most certified public and private health facilities.

Note: Untrained/unregistered providers often perform abortions and PAC, which can lead to complications. Please try to ensure your chosen provider is certified and trained in comprehensive abortion care.

Responsive image

What is the cost of a safe abortion or PAC in Nigeria?

The cost of legal abortions and PAC services differ by facility (private or public) and provider depending on the method (medical or surgical), complications and severity of symptoms. The costs can range from USD 3.00 - USD 103.00.

Responsive image

What abortion and PAC drugs are available in Nigeria?

 • Misoprostol is available under the brand names Cytotec, Miso-fem and Vanaprazol - 200
 • Mifepristone is available as a combipack under the brand name Mifepack

Note: Misoprostol is only registered in Nigeria for the treatment of Post-Partum hemorrhage (PPH), however it can also be safely used for a medical abortion within 10 weeks following proper dosage and use.

Responsive image

Can I buy abortion pills at a pharmacy in Nigeria?

 • Misoprostol under the brand name Cytotec can be bought at pharmacies but can only be issued with an accompanying prescription.
 • The pill usually costs between USD 3.00 – USD 9.00.

Note: Many pharmacists do sell Misoprostol without a prescription, however they do not often provide proper instructions on eligibility, dosage and usage for a medical abortion. Please refer to the following page on our website for comprehensive instructions on how to use the pill: https://www.howtouseabortionpill.org/howto/#mi

Responsive image

Who can I contact for additional abortion information and support in Nigeria?

Was this useful? What else would you like to see here?
Contact us at: info@howtouseabortionpill.org


References:

 • 1. Cost-effectiveness analysis of unsafe abortion and alternative first-trimester pregnancy termination strategies in Nigeria and Ghana.” African Journal of Reproductive Health, ResearchGate. https://www.researchgate.net/publication/49763986_Cost-effectiveness_analysis_of_unsafe_abortion_and_alternative_first-trimester_pregnancy_termination_strategies_in_Nigeria_and_Ghana
 • 2. “Facts on Unwanted Pregnancy and Induced Abortion in Nigeria.” Guttmacher Institute. https://www.guttmacher.org/sites/default/files/factsheet/fb_nigeria.pdf
 • 3. “Impact of abortion laws on women's choice of abortion service providers and facilities in southeastern Nigeria.” Nigerian Journal of Clinical Practice. http://www.njcponline.com/article.asp?issn=1119-3077;year=2018;volume=21;issue=9;spage=1114;epage=1120;aulast=Chigbu
 • 4. “An Abortion Pill in a Murky Market.” Pulitzer Center. https://pulitzercenter.org/reporting/abortion-pill-murky-market
Responsive image

Àwọn òfin oyún ṣíṣẹ́ ní ilẹ̀ Nàìjíríà.

Responsive image

Ṣé òfin gba oyún ṣíṣẹ́ láàyè ní Nàìjíríà?

Ní ilẹ̀ Nàìjíríà, kò sí ìgbàláàyè fún oyún ṣíṣẹ́ àyàfi tí ẹ̀mí aláboyún bá wà nínú ewu. Òfin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ méjì ni ó wà fún oyún ṣíṣẹ́ ní ilẹ̀ Nàìjíríà, ọkàn ní apá àríwá, ọkàn ní gúúsù. Òfin apá gúúsù faramọ́ ọ tí oyún náà bá lè pa àlàáfíà ara àti ọpọlọ aláboyún lára. Àwọn Mùsùlùmí ni ó pọ̀ jù ní apá àríwá tí ó sì jẹ́ pé òfin kóòdù ìjìyà tí a mọ̀ sí "penal code", tí wọ́n sì ń lo òfin kóòdù tí a mọ̀ sí "criminal code" ní apá gúúsù tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti jẹ́ ẹlẹ́sìn ìgbàgbọ́.

Ní ọdún 1982, ẹgbẹ́ àwọn oníṣègùn tí ó ní ṣe pẹ̀lú ọmọ bíbí àti àwọn tí ó ní ṣe pẹ̀lú àwọn àrùn tí ó ń gbógun ti àwọn ẹ̀yà ara obìnrin tí ó ní ṣe pẹ̀lú ọmọ bíbí fi ọwọ́ sí ìwé òfin tí yóò fi kún àwọn ohun tí ó lè fa ìgbàláàyè oyún ṣíṣẹ́. Ìwé òfin yìí ò bá fi ààyè gba ṣíṣẹ́ oyún tí ó bá lè kóbá àlàáfíà àwọn ọmọ tí aláboyún náà ti bí tẹ́lẹ̀ tàbí tí ó ṣeéṣe kí ó fi oyún náà bí ọmọ alaábọ̀ ara tàbí tí ọpọlọ rẹ kò ní dápé ṣùgbọ́n àwọn aṣáájú ẹ̀sìn àti àjọ àwọn ẹgbẹ́ obìnrin ní ilẹ̀ Nàìjíríà takò ó. Wọ́n ní yóò fa ìfẹ́kúfẹ́ àti ìranù nínú àwùjọ. Títí di òní, kò sí ìyípadà kankan nínú òfin tí ó de oyún ṣíṣẹ́.

Responsive image

Kí ni àwọn ìtọ́jú tí ó wà fún aláboyún lẹ́yìn oyún ṣíṣẹ́ nílẹ́ Nàìjíríà?

 • Àwọn ọ̀nà tí ó jẹ mọ́ ìṣègùn òyìnbó: Lílo àwọn òògùn bíi misoprostol (lábẹ́ orúkọ Cycotec, Miso Fem, Vanprazol-200)
 • Àwọn ọ̀nà tí ó jẹ mọ́ iṣẹ́ abẹ: Fífa oyún síta (Manual vacuum Aspiration)
Responsive image

Àwọn wo ni ó lè bá ènìyàn ṣẹ́ oyún, tí ó sì lè ṣe ìtọ́jú ẹ̀yìn oyún ṣíṣẹ́ fún un ní ọ̀nà tí ó bófin mu ni ilẹ̀ Nàìjíríà?

Àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ elétò ìlera tí wọ́n ní ìwé àṣẹ, ní ilé ìwòsàn ìjọba tàbí aládàáni nìkan ni òfin fààyè gbà láti ṣẹ́ oyún àti láti ṣe ìtọ́jú ẹ̀yìn oyún ṣíṣẹ́.

Àkíyèsí: Òfin fi ààyè gba elétò ìlera láti kọ̀ láti ṣẹ́ oyún tí ẹ̀sìn, àṣà, ìṣe tàbí ìwà wọn ò bá rọ̀ mọ́ ọ.

Responsive image

Níbo ni mo lè lọ láti ṣẹ́ oyún àti láti gba ìtọ́jú ẹ̀yìn oyún ṣíṣẹ́ ní ọ̀nà tí ó bófin mu?

Àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ elétò ìlera tí ó ní ìwé àṣẹ nìkan ni òfin fààyè gbà láti ṣẹ́yún àti láti ṣe ìtọ́jú ẹ̀yìn oyún ṣíṣẹ́. O lè rí wọn ní ilé ìwòsàn ìjọba tàbí ti aládàáni tí ìjọba fi ọwọ́ sí.

Àkíyèsí: Àwọn elétò ìlera kọ̀lọ̀rọ̀sí tí kò kọ́ṣẹ́mọṣẹ́ tí kò sì ní ìwé àṣẹ náà máa ń ṣẹ́ oyún tàbí ṣe ìtọ́jú ẹ̀yìn oyún ṣíṣẹ́ ṣùgbọ́n ó ṣeéṣe kí ó yíwọ́. Jọ̀wọ́, lọ sí ọ̀dọ̀ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ elétò ààbò tí ó ní ìwé àṣẹ tí ó bá fẹ́ ṣẹ́yún.

Responsive image

Èló ni a lè ṣẹ́yún tàbí gba ìtọ́jú ẹ̀yìn oyún ṣíṣẹ́ ní ọ̀nà tí kò béwu dé ní ilẹ̀ Nàìjíríà?

Owó oyún ṣíṣẹ́ àti ìtọ́jú ẹ̀yìn rẹ̀ máa ń yàtọ̀. Ìyàtọ̀ yìí máa ń dá lórí irú ilé ìwòsàn tí ó jẹ́ (ti ìjọba tàbí aládàáni), elétò ààbò tí ó bá jẹ́, ọ̀nà tí wọ́n máa ń gbà (òògùn lílò tàbí iṣẹ́ abẹ), ewu tí ó bá dé, àti bí àwọn àpẹẹrẹ náà bá ṣe le tó. Owo náà lè wà láàrin dọ́là mẹ́ta sí mẹ́tàlẹ́lọ́gọ́rùn ún (USD3.00 - USD103.00).

Responsive image

Irú òògùn oyún ìṣẹ́yún àti ìtọ́jú ẹ̀yìn rẹ̀ wo ni ó wà ní Nàìjíríà?

 • Misoprostol wà (lábẹ́ àwọn orúkọ bíi Cycotec, Miso-fem àti Vanaprazol-200.
 • Mifepristone náà wà ní àpapọ̀ pẹ̀lú orúkọ Mifepack.

Àkíyèsí: Ohun tí ààyè lílo misoprostol wà fún ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni láti fi dá ẹ̀jẹ̀ ìbímọ dúró ṣùgbọ́n ó lè fi ṣẹ́yún ní ìlànà ìṣègùn òyìnbó láìsí wàhálà tí oyún náà ò bá tíi ju ọ̀sẹ̀ mẹ́wàá lọ tí ó sì tẹ̀lé ọ̀nà tí a là kalẹ̀.

Responsive image

Ǹjẹ́ mo lè ra òògùn oyún ṣíṣẹ́ ní àwọn ilé ìtajà òògùn ní Nàìjíríà?

 • O lè ra Misoprostol lábẹ́ orúkọ Cycotec ní àwọn ilé ìtajà òògùn tí ó bá ní ìwé ìjúwe láti ọ̀dọ̀ elétò ààbò.
 • Owo rẹ ò ju dọ́là mẹ́ta sí mẹ́sàn-án lọ (USD3.00 - USD9.00)

Àkíyèsí: Ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùtajà òògùn máa ń ta misoprostol láìsí ìwé ìjúwe yìí ṣùgbọ́n wọn ò ní sọ ẹni tí ó lè lò ó, bí wọn ó ṣe lò ó àti iye tí wọn ó lò. Jọ̀wọ́, lọ sí https://www.howtouseabortionpill.org/howto/#mi fún àlàyé kíkún nípa bí a ṣe ń lo òògùn ìṣẹ́yún.

Responsive image

Ta ni mo lè kàn sí fún àlàyé síwájú síi nípa oyún ṣíṣẹ́ àti ìtọ́jú ní ilẹ̀ Nàìjíríà?

 • Ms Rosy Hotline http://giwynn.org/ms-rosy-hotline/ – máa ń ṣe àlàyé nípa ìlera àti ẹ̀tọ́ tí ó jẹ mọ́ ọmọ bíbí àti ìbálòpọ̀ fún àwọn obìnrin. O lè pe aago wọn ní ìgbàkigbà tí o bá fẹ́ lọ́fẹ̀ẹ́.
  Pe: +1855 553 1550 OR 08097737600 OR 08097738001
  Facebook: https://web.facebook.com/msrosyhotline/?_rdc=1&_rdr
 • Àjọ tí ó ń mójútó ìlera ìbí àti ti gbogbo ẹbí (ARFH) http://arfh-ng.org/ - máa ń ṣiṣẹ́ láti mú àgbéga bá ìlera àti ẹ̀tọ́ tí ó jẹ mọ́ ìbí àti ìbálòpọ̀ ní Nàìjíríà.
  Nọ́mbà ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀: +234 2 751 5772 (Ojúmọmọ) tàbí +234 802 354 2889 OR +234 706 596 4489
  Facebook: https://web.facebook.com/arfhng?_rdc=1&_rdr
 • Marie Stopes ti ilẹ̀ Nàìjíríà. (https://www.mariestopes.org.ng/ ) – máa ń pèsè ìtọ́jú ẹ̀yìn oyún ṣíṣẹ́, ìdènà oyún, ìfètòsọ́mọbíbí àti àwọn ìlera gbogbogboo.
  Nọ́mbà ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ (ọ̀fẹ́, àṣírí): 08000022252
  Nọ́mbà whatsapp: 08090022252
  Facebook: https://web.facebook.com/MarieStopesNG/?_rdc=1&_rdr
 • Àjọ ìfètò sí jíjẹ́ òbí ní ilẹ̀ Nàìjíríà (PPFN) http://www.ppfn.org/ - máa ń ṣe àtílẹ́yìn nípa ìlera ìbálòpọ̀ àti ìbí, wọ́n sì máa ń jà fún àwọn ẹ̀tọ́ tí ó rọ̀ mọ́ ọ.
  Nọ́mbà: +2347085472059, +2347085472047, +2348033048146
  Facebook: https://web.facebook.com/ppfnigeria/

Ṣé ó wúlò fún ọ? Kí ni ó tún wù ọ́ kí ó rí níbí?
Kàn sí wa ni: info@howtouseabortionpill.org


Àwọn atọ́ka:

 • 1. Cost-effectiveness analysis of unsafe abortion and alternative first-trimester pregnancy termination strategies in Nigeria and Ghana.” African Journal of Reproductive Health, ResearchGate. https://www.researchgate.net/publication/49763986_Cost-effectiveness_analysis_of_unsafe_abortion_and_alternative_first-trimester_pregnancy_termination_strategies_in_Nigeria_and_Ghana
 • 2. “Facts on Unwanted Pregnancy and Induced Abortion in Nigeria.” Guttmacher Institute. https://www.guttmacher.org/sites/default/files/factsheet/fb_nigeria.pdf
 • 3. “Impact of abortion laws on women's choice of abortion service providers and facilities in southeastern Nigeria.” Nigerian Journal of Clinical Practice. http://www.njcponline.com/article.asp?issn=1119-3077;year=2018;volume=21;issue=9;spage=1114;epage=1120;aulast=Chigbu
 • 4. “An Abortion Pill in a Murky Market.” Pulitzer Center. https://pulitzercenter.org/reporting/abortion-pill-murky-market

This website may require anonymous cookies and various third party services to function properly. You can read our Terms & Conditions and Privacy Policies. By continuing to use this site you are giving us your consent to do this.