Ta ni ó lè lo òògùn oyún ṣíṣẹ́?

Mo ṣe iṣẹ́ abẹ ìsọnidi aláìlèbímọ. Kò ṣiṣẹ́, mo sì lóyún. Inú ọ̀nà tí ẹyin máa ń gbà dé ilé ọmọ ni oyún náà wà. Mo tún ti wá lóyún. Ṣé kò ní pa mí lára tí mo bá ṣẹ́yún?

Rárá o, ó léwu láti lo òògùn ìṣẹ́yún nígbà tí ó ṣeéṣe kí oyún náà má wà nínú ilé ọmọ. Nítorí pé o ti ṣe iṣẹ́ abẹ ìsọnidi àláìlèbímọ, apá wà nínú ọ̀nà tí ẹyin ń gbà dé ilé ọmọ, ó súnmọ́ kí ó jẹ pe oun ni ìdí tí oyún tí o ní kẹ́yìn ṣe bọ́ sí inú rẹ̀. Inú ọ̀nà yìí ni àtọ̀ ti máa ń sọmọ. Tí oyún bá ti ń dàgbà, yóò máa lọ sí ilé ọmọ ṣùgbọ́n nítorí pé apá ti wà ní ọ̀nà náà, kò lè ráyè kọjá. Oyún náà ó sì máa dàgbà sí ibi tí ó wà. Bí ó ṣe ń dàgbà síi, inú ọ̀nà tí o wà lè bẹ́, èyí tí ó lè fa kí ẹ̀jẹ̀ máa ya nínú rẹ, ní èyí tí ó léwu. Ó ṣeéṣe kí oyún eléyìí náà má sí nínú ilé ọmọ. Má ṣe dá òògùn oyún ṣíṣẹ́ lò fúnraàrẹ àyàfi tí elétò ààbò bá rí àrídájú pé inú ilé ọmọ ni oyún náà wà.


References

This website may require anonymous cookies and various third party services to function properly. You can read our Terms & Conditions and Privacy Policies. By continuing to use this site you are giving us your consent to do this.