Ṣíṣẹ́ oyún tí ó ti pé ọ̀sẹ̀ mẹ́wàá sí mọ́kànlá ní ìlànà ìṣègùn òyìnbó.

Ó sì lè ṣẹ́ oyún ọ̀sẹ̀ mẹ́wàá sí mọ́kànlá pẹ̀lú òògùn ìṣẹ́yún ní ìlànà ìṣègùn òyìnbó láìsí ewu, ṣùgbọ́n àwọn nǹkan wà tí a gbọ́dọ̀ ro.

Àìléwu oyún ṣíṣẹ́ pẹ̀lú ọ̀sẹ̀.

Tí o bá ṣẹ́yún ní àìpẹ́ tí o níi, kò sí ewu púpọ̀. Bí oyún náà ṣe ń dàgbà síi ni ewu náà ń pọ̀ síi, àwòrán tí ó wà ní ìsàlẹ̀ yìí sàfihàn èyí. Lóòótọ́, bí oyún ṣe ń dàgbà ni ewu ń pọ̀ síi, ṣùgbọ́n oyún ọ̀sẹ̀ mọ́kànlá sì ṣé é ṣẹ́ láìsí ewu ní ìlànà ìṣègùn òyìnbó.

Bí oyún àwọn obìnrin

tí ó nílò ìtọ́jú síi ṣe dàgbà sí.

  • 0- 49 Ọ́jọ́ (0-7 Ọ̀sẹ̀)
  • 40-63 Ọ́jọ́ (7-9 Ọ̀sẹ̀)
  • 64-70 Ọ́jọ́ (9-10 Ọ̀sẹ̀)
  • 71-77 Ọ́jọ́ (10-11 Ọ̀sẹ̀)
  • 2%
  • 2.5%
  • 2.7%
  • 3.3%

Láti: https://www.womenonweb.org/

Àwọn nǹkan wo ni ó máa rí tí ó bá ṣẹ́ oyún tí ó ti ju ọ̀sẹ̀ mẹ́wàá lọ?

Oyún ṣíṣẹ́ ní ìlànà ìṣègùn òyìnbó máa ń jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ yọ lára àwọn obìnrin. Ẹ̀jẹ̀ yìí lè pọ̀ ju ti nǹkan oṣù lọ, ẹ̀jẹ̀ dídì sì lè wà níbẹ̀. Ó ṣeéṣe kí àwọn tí oyún wọn bá wà láàrin ọ̀sẹ̀ mẹ́wàá sí mọ́kànlá rí ohun tí wọn ò dá mọ̀, tàbí tí ó jọ awọ kékeré. Eléyìí ò kí ń ṣe nǹkan èèmọ̀, má ṣe jáyà. Ara àwọn àmì pé oyún náà ti ń wálẹ̀ bí ó ṣe yẹ ní. O lè da ẹ̀jẹ̀ dídì tàbí awọ náà sí inú ilé ìgbọ̀nsẹ̀, bíi nǹkan oṣù. Tí òfin bá lòdì sí oyún ṣíṣẹ́ ní agbègbè rẹ, sọra tí o bá fẹ́ sọ àwọn ohun tí àwọn ènìyàn lè dámọ̀ nù. Má sì ṣe sọ ọ́ sí ibi tí àwọn ènìyàn yóò ti ríi.


Àwọn atọ́ka:

This website may require anonymous cookies and various third party services to function properly. You can read our Terms & Conditions and Privacy Policies. By continuing to use this site you are giving us your consent to do this.