Ki o tó lo òògùn náà

Ẹ̀rọ ìṣirò oyún

Ó tó ọ̀sẹ̀ mélòó tí ó lóyún? Ìwádìí tí fihàn pé oyún tí kò bá tíì tó ọ̀sẹ̀ mẹ́wàá lẹ́yìn nǹkan oṣù ìkẹ́yìn ni wọn sáábà máa ń fara mọ́ kí èèyàn ṣé. Fi ẹ̀rọ ìṣirò oyún ṣírò iye ọ̀sẹ̀ tí oyún rẹ ti pé lẹ́yìn tí ó ṣe nǹkan oṣù kẹ́yìn.

Tí nǹkan oṣù rẹ bá bẹ̀rẹ̀ ní tàbí lẹ́yìn:

Ó sì lè lo òògùn ìṣẹ́yún.

Àwọn èrò

Considerations illustration 01
 • Tí ẹ̀rọ ìdènà oyún (òníkíká tàbí èyí tí ó ní "progesterone" nínú) bá wà nínú ilé ọmọ, o gbọ́dọ̀ yọọ́. Dandan ni kí o yọ ẹ̀rọ ìdènà oyún kí o tó lo òògùn ìṣẹ́yún.
Considerations illustration 03
 • Tí o ò bá fẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀ nípa oyún tí o fẹ́ ṣẹ́, o lè lo òògùn náà ní kọ̀rọ̀ ẹ̀ẹ̀kẹ̀ dípò lójú ara. Tí ó bá fẹ́ ní àwọn ìṣòro kan, èyí kò súnmọ́ kí ó ṣẹlẹ, tí o sì nílò ìtọ́jú elétò ààbò, ó ṣeéṣe kí wọ́n rí òògùn náà ní ojú ara rẹ. Èyí lè mú kí wọ́n fi ẹjọ́ rẹ sún ní ìlú tí òfin ò fààyè gba oyún ṣíṣẹ́.
Considerations illustration 05
 • Tí o bá ní àrùn anémíà (tí áyọ́ọ̀nù ò bá tó nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ), wá elétò ààbò tí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ò ju ọgbọ̀n ìṣẹ́jú lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ nítorí bí ó bá nílò ìrànlọ́wọ́. Tí anémíà rẹ bá lè, bá dókítà sọ̀rọ̀ kí o lo òògùn ìṣẹ́yún.
Considerations illustration 02
 • Tí ó bá ní kòkòrò àrùn kògbóògùn HIV lára, ríi dájú pé àárẹ̀ ò mú ọ, o ń lo òògùn rẹ déédé, ara rẹ sì yá.
Considerations illustration 04
 • Tí o bá ń fọ́mọ lọ́yàn lọ́wọ́ tí o fi lo misoprostol, ọmọ náà lè ní ìgbẹ́ gbuuru. Láti dènà èyí, dúró fún bíi wákàtí mẹ́rin lẹ́yìn tí o bá lo òògùn yìí tán kí o tó tún fún ọmọ lọ́yàn.

Ìmọ̀ràn

General_illustration_01
 • Mu ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi ní àkókò tí o bá ń ṣẹ́yún.
General_illustration_02
 • Wà ní ibi tí ó pamọ́ tí o sì ti lè fẹ̀gbẹ́ lélẹ̀ fún wákàtí díẹ̀ lẹ́yìn tí o bá lo òògùn tán kí o tó lo misoprostol.
General_illustration_03
 • Rọra jẹun (o lè jẹ bisikíítì pẹlẹbẹ tí ò ní ṣúgà tàbí tósíìtì láti dín ebi kù).
General_illustration_04
 • Yóò dára bí ẹnìkan bá le dúró tì ọ láti ṣe ìtọ́jú rẹ.
General_illustration_05
 • O lè lo òògùn "ibuprofen" kí o tó lo misoprostol láti dín ìnira inú fífúnpọ̀ kù.
General_illustration_06
 • Ṣe ètò ààbò kí o tó lo òògùn ìṣẹ́yún nítorí tí o bá nílò ìtọ́jú pàjáwìrì.

Ṣíṣe ètò ààbò

Gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ àwọn oníṣègùn tí ó ní ṣe pẹ̀lú ọmọ bíbí àti àwọn tí ó ní ṣe pẹ̀lú àwọn àrùn tí ó ń gbógun ti àwọn ẹ̀yà ara obìnrin tí ó ní ṣe pẹ̀lú ọmọ bíbí ti ìlú Amẹ́ríkà, ṣíṣẹ́ oyún ní ìlànà ìṣègùn òyìnbó ní ìdá àkọ́kọ́ nínú mẹ́ta àkókò oyún jẹ́ ọ̀kan tí kò mú ewu lọ́wọ́. O lè lo àwọn ìbéèrè tí a fi sí ìsàlẹ̀ yìí láti ṣe ètò ààbò rẹ torí a ò mọ ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀.

Níbo ni ilé ìwòsàn pàjáwìrì tí ó máa ń ṣí yíká aago tí ó súnmọ́ jù wà?

Ó gbọ́dọ̀ lè débẹ̀ láàrin wákàtí kan (tí o bá ní anémíà, o gbọ́dọ̀ lè débẹ̀ láàrin ọgbọ̀n ìṣẹ́jú)

Creating_illustration_01
Creating_illustration_02

Báwo ni o ṣe máa dé ilé ìwòsàn pàjáwìrì náà?

Ṣe ẹni tí ó lè wà ọ́ yóò wà? Ṣé takisí lo fẹ́ wọ̀ ni àbí ọkọ èrò? Èló ni owó ọkọ̀ àti pé ṣé ó máa ń ṣiṣẹ́ yíká aago? Má ṣe gbàgbé pé ó léwu láti wa ara rẹ lọ sí ilé ìwòsàn ní irú àsìkò yìí.

Kí ni o máa sọ fún àwọn dókítà rẹ?

Ṣe òfin fi ààyè gba oyún ṣíṣẹ́ ni ìlànà ìṣègùn òyìnbó tàbí ní ilé ní ibi tí ò ń gbé? Kí ni o lè sọ fún wọn tí wọn yóò fi mọ̀ pé o nílò ìtọ́jú tí kò ní kóbá ọ? Tí o bá ń wá ohun tí o lè sọ, wo àwọn àbá tí ó wà ní ìsàlẹ̀ yìí

Creating_illustration_03
Creating_illustration_04

Ohun tí o máa sọ fún àwọn dókítà

Ní àwọn orílẹ̀ èdè kan, oyún ṣíṣe ní ìlànà ìṣègùn oyinbo tàbí ní ilé lòdì sí òfin. Èyí túmọ̀ sí pé ó gbọ́dọ̀ mọ ohun tí o máa sọ fún àwọn dókítà bí o bá nílò ìtọ́jú pàjáwìrì tí kò ní ṣàkóbá fún ọ. Àwọn àmì oyún ṣíṣe ní ìlànà ìṣègùn òyìnbó ò yàtọ̀ sí ìgbà tí oyún bá wálẹ̀ fúnraarẹ̀. O lè sọ àwọn nǹkan bíi

 • Ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ ò yé mi. Ẹ̀jẹ̀ kàn bẹ̀rẹ̀ sí yọ ni
 • Ẹ̀jẹ̀ ń yọ ṣùgbọ́n kò dà bíi tí nǹkan oṣù.
 • Ẹ̀jẹ̀ kàn ń déédéé yọ ni. Ẹrú sì ń bà mí nítorí mi ò mọ ohun tí ó le fà á

Àwọn òǹkọ̀wé:

Gbogbo àkóónú tí a fihàn lórí ayélujára yìí ni a kọ nípa ẹgbẹ́ HowToUseAbortionPill.org ní ìbámu pẹ̀lu àwọn òṣùwọ̀n àti ìlànà láti Àjọ Àpapọ̀ Oyún ṣíṣẹ́ [The National Abortion Federation], Ipas, Àjọ tí ó ńbójútó Ìlera L’ágbàyé [the World Health Organization], DKT L’ágbàyé àti carafem.

Àjọ Àpapọ̀ Oyún ṣíṣẹ́ (NAF) jẹ́ ẹgbẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ àwọn olùpèsè oyún ṣíṣẹ́ ní Àríwá Amẹ́ríkà, àti aṣíwájú ní ìgbìyànjú fún yíyàn láti yọ oyún. Àkóónú lórí HowToUseAbortionPill.org wà ní ìbámu pẹ̀lu 2020 Àwọn ìtọ́ni Òfin Ìṣègùn tí NAF gbéjáde.

Ipas jẹ́ ẹgbẹ́ kansoso ní àgbàyé tí ó ńtẹjúmọ́ mímú kí rírí ààyè sí oyún ṣíṣẹ́ láìsí ewu àti àbójútó dídènà oyún níní fẹ̀ si. Àkóónú lórí HowToUseAbortionPill.org wà ní ìbámu pẹ̀lu Ìmúdójú-ìwọ̀n Ìléra Bíbímọ 2019 tí Ipas gbéjáde.

Àjọ tí ó ńbójútó Ìlera L’ágbàyé (WHO) jẹ́ àjọ tí ó mọ nǹkan lámọ̀já ti ẹ̀ka Àjọ Àpapọ̀ orílẹ̀-èdè L’ágbàyé tí ó ní ojúṣe fún ìlera àwùjọ l’ágbàyé. Àkóónú lórí HowToUseAbortionPill.org wà ní ìbámu pẹ̀lu 2012 Oyún ṣíṣẹ́ láìsí ewu: ìtọ́ni iṣẹ́ ọnà àti òfin fún ètò ìlera tí WHO gbéjáde.

DKT L’ágbàyé jẹ́ àjọ tí a ti forúkọ rẹ̀ sílẹ̀, tí kò sí fún èrè tí a dá sílẹ̀ ní ọdún 1989 láti tẹjúmọ́ agbára ìlànà mímú àwùjọ yípadà fún àǹfààní àwùjọ ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ṣe àìní tí ó gá jù lọ fún fífi ètò sí ọmọ bíbí, dídènà HIV/AIDS àti oyún ṣíṣẹ́ láìsí ewu.

carafem jẹ́ alátagbà ìṣègùn tí ó ńpèsè oyún ṣíṣẹ́ láìsí ewu èyìtí ó rọrùn àti fífi ètò sí ọmọ bíbí nípasẹ̀ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ kí àwọn ènìyàn lè ṣe àkóso iye àwọn ọmọ àti àlàfo tí ó wà láàrín wọn.


Àwọn ìtọ́ka:

This website may require anonymous cookies and various third party services to function properly. You can read our Terms & Conditions and Privacy Policies. By continuing to use this site you are giving us your consent to do this.