Bẹ́ẹ̀ni, iye òògùn kan náà ni gbogbo ènìyàn máa lo. Ìwádìí fi hàn pé iṣẹ́ òògùn náà ò kan bí èèyàn bá ṣe tóbi tó. O ò nílò òògùn púpọ̀ tàbí ìlànà mìíràn.
Àwọn ìbéèrè tí àwọn èèyàn sáábà máa ń béèrè nípa oyún ṣíṣẹ́
Ta ni ó lè lo òògùn oyún ṣíṣẹ́?
Ìlànà kan náà ni ó wà fún oyún ìbejì, o ò ní láti lo òògùn púpọ̀.
Bẹ́ẹ̀ni, oyún kọ̀ọ̀kan yàtọ̀ gédégbé sí ara wọn. Kódà kí o ti lò ó rí, nǹkan tí o lò ní àkọ́kọ́ náà ni ó máa lò fún oyún mìíràn tí o fẹ́ ṣẹ́.
Tí ẹ̀rọ ìdènà oyún (èyí tí wọ́n ká tàbí èyí tí ó ní hòmóònù “progesterone” nínú) bá wà nínú ilé ọmọ rẹ, o gbọ́dọ̀ yọ ọ́ kí o tó ṣẹ́yún náà.
Tí o bá ń fọ́mọ lọ́yàn, misoprostol lè fa ìgbẹ́ gbuuru fún ọmọ náà. Láti dènà èyí, dúró fún wákàtí mẹ́rin lẹ́yìn tí o bá lo òògùn tán kí o tó fọ́mọ lọ́yàn.
Tí o bá ní HIV, ríi dájú pé àárẹ̀ ò mú ọ, o sì ń lo òògùn tí ó ń gbógun ti kòkòrò àìfojúrí HIV (antiretroviral).
Tí o bá ní anémíà (àìtó áyọ́ọ̀nù nínú ẹ̀jẹ̀), wá elétò ìlera tí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ò jìnà ju ọgbọ̀n ìṣẹ́jú sí ọ̀dọ̀ rẹ lọ tí ó sì lè ṣe ìtọ́jú rẹ tí o bá nílò rẹ̀. Tí anémíà rẹ bá lè, gba àṣẹ dókítà kí o tó lo òògùn ìṣẹ́yún.
Rárá, kò sí ewu tí ò bá ti ṣẹ́ oyún náà láìpẹ́ tí o ní i kódà kí o ti bímọ pẹ̀lú iṣẹ́ abẹ rí.
Kò tíì sí àsopọ̀ láàrín mifepristone àti àbùkù ara ọmọ ṣùgbọ́n misoprostol lè mú u ṣẹlẹ̀. Tí o bá lo misoprostol tí oyún náà sì wà lára rẹ, ó ṣeéṣe kí oyún náà wálẹ̀ fúnraàrẹ. Tí oyún náà ò bá sì wálẹ̀ títí àkókò ìbí fi tó, ewu kí ọmọ náà ní àbùkù lára jẹ́ idà kan nínú ọgọ́rùn-ún (1%)
Rárá o, ó léwu láti lo òògùn ìṣẹ́yún nígbà tí ó ṣeéṣe kí oyún náà má wà nínú ilé ọmọ. Nítorí pé o ti ṣe iṣẹ́ abẹ ìsọnidi àláìlèbímọ, apá wà nínú ọ̀nà tí ẹyin ń gbà dé ilé ọmọ, ó súnmọ́ kí ó jẹ pe oun ni ìdí tí oyún tí o ní kẹ́yìn ṣe bọ́ sí inú rẹ̀. Inú ọ̀nà yìí ni àtọ̀ ti máa ń sọmọ. Tí oyún bá ti ń dàgbà, yóò máa lọ sí ilé ọmọ ṣùgbọ́n nítorí pé apá ti wà ní ọ̀nà náà, kò lè ráyè kọjá. Oyún náà ó sì máa dàgbà sí ibi tí ó wà. Bí ó ṣe ń dàgbà síi, inú ọ̀nà tí o wà lè bẹ́, èyí tí ó lè fa kí ẹ̀jẹ̀ máa ya nínú rẹ, ní èyí tí ó léwu. Ó ṣeéṣe kí oyún eléyìí náà má sí nínú ilé ọmọ. Má ṣe dá òògùn oyún ṣíṣẹ́ lò fúnraàrẹ àyàfi tí elétò ààbò bá rí àrídájú pé inú ilé ọmọ ni oyún náà wà.
Àkọ́kọ́ náà, ó gbọ́dọ̀ mọ̀ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìnrin ò ní mọ̀ pé àwọn ní irú oyún báyìí àfi tí wọ́n bá ya àwòrán inú. Oyún inú ọ̀nà yìí léwu débi pé àwọn orílẹ̀-èdè tí òfin ò ti fààyè gba oyún ṣíṣẹ́ gan-an fi ọwọ́ sí kí wọn ṣẹ oyún yìí.

Oríṣiríṣi àwọn òògùn ìṣẹ́yún tí ó wà àti lílò wọn
Oríṣi òògùn ìṣẹ́yún méjì ni ó wà, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan sì ń ṣiṣẹ́ ní ìlànà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Mifepristone máa ń dá ìpèsè hòmóònù tí ó máa ń mú oyún dàgbà dúró. Àwọn èròjà inú misoprostol sì máa ń ṣí àti de ẹnu ọ̀nà ilé ọmọ ní sísẹ̀ntẹ̀lé, a sì máa fún ilé ọmọ pọ̀, èyí tí yóò ti oyún náà jáde.
Misoprostol máa ń fún ilé ọmọ pọ̀ tí oyún náà yóò fi jáde.
Mifepristone máa ń dènà hòmóònù tí ó máa ń jẹ́ kí oyún dàgbà.
Bẹ́ẹ̀ni, o lè lo misoprostol nílé láìsí ewu. Tí o bá lò ó, gbìyànjú kí o wà níbi tí èrò kò pọ̀ sí (bí ilé rẹ) tí o sì lè fẹ̀gbẹ́ lélẹ̀ fún wákàtí díẹ̀ lẹ́yìn tí o bá lò ó tán. Yóò dára tí ẹnìkan bá wà pẹ̀lú rẹ tí ó lè tọ́jú rẹ, tí ò sì lè po tíì gbígbóná tàbí bá ọ wá nǹkan láti jẹ.
Má ṣe mu tàbí jẹ ohunkóhun láàrin ọgbọ̀n ìṣẹ́jú tí o bá lo misoprostol kí òògùn náà fi túká. Lẹ́yìn ọgbọ̀n ìṣẹ́jú, o lè mu omi láti ṣan òògùn tí ó bá kù ní ẹnu rẹ nu kí o lè gbé e mi àti láti stay hydrated.
Bẹẹni, o le mu omi lati ṣe iranlọwọ fun ọ lati gbe mì mifepristone.
Awọn ọna meji lo wa lati lo misoprostol: gbigbe rẹ sinu obo rẹ tabi labẹ ahọn rẹ (sublingually). HowToUse ṣe imọran pe o lo misoprostol nikan labẹ ahọn rẹ nitori pe o jẹ ikọkọ diẹ sii (awọn oogun naa tuka yiyara ati pe ko fi awọn ami ti o han silẹ si ara rẹ) ati pe o ni kere eewu ti akoran.
Méjèèjì: Lílo misoprostol nìkan àti lílo ó pẹ̀lú mifepristone ni ó máa ń ṣiṣẹ́ dáadáa. Ṣùgbọ́n tí o bá wà, tí agbára rẹ sì káa, mifepristone àti misoprostol ni kí o lò.
Oyún méjìdínlọ́gọ́rùn ún nínú ọgọ́rùn-ún (98%) yóò wálẹ̀ pẹ̀lú àlòpọ mifepristone àti misoprostol nígbà tí misoprostol nìkan máa ń mú oyún márùnlélàádọ́rùn ún wálẹ̀.
Mifepristone àti misoprostol a máa ṣiṣẹ́ papọ̀ tí o bá lò wọ́n pọ̀. Èròjà tí ó wà nínú misoprostol máa ń ṣí àti tí ẹnu ọ̀nà ilé ọmọ, èyí tí yóò mú kí ilé ọmọ fún pọ̀ tí oyún náà yóò sì jáde.
Tí ó bá lo misoprostol lábẹ́ ahọ́n, kò sí ẹnikẹ́ni tí ó máa mọ̀ pé o lo òògùn ìṣẹ́yún nítorí pé o máa gbé e mì lẹ́yìn ọgbọ̀n ìṣẹ́jú. O sì lè sọ fún ẹnikẹ́ni tí ó bá béèrè pé oyún náà wálẹ̀ fúnraàrẹ ni. Tí o bá lo misoprostol ní ojú ara, ara ohun tí wọ́n fi pèèlò rẹ̀ lè lò tó ọjọ́ kan tàbí méjì kí ó tó tú tán. Elétò ìlera sì lè rí nǹkan funfun ni ojú ara rẹ tí o bá nílò ìtọ́jú pàjáwìrì láàrín wákàtí méjìdínlàádọ́ta tí o bá lò ó. Ìdí nìyí tí a fi gbà ọ́ nímọ̀ràn pé kí o lo òògùn náà ní abẹ́ ahọ́n dípò ojú ara.

Àwọn ohun tí ó lè mú kí èèyàn má lè lo òògùn náà.
Má ṣe lo òògùn ìṣẹ́yún ní ilé tí oyún rẹ bá ti ju ọsẹ̀ 13 lọ; tí mifepristone tàbí misoprostol bá jẹ́ èèwọ̀ ara rẹ; tí ìlera rẹ ò bá péye tó, tí o bá ní ìṣòro ẹ̀jẹ̀ dídì; tí o bá rò tàbi mọ̀ pé inú ilé ọmọ rẹ kọ́ ni oyún náà wà.

Àwọn ìpalára àti ìṣòro òògùn ìṣẹ́yún
Fún àwọn kan, ìnira a máa pọ̀ ju ti nǹkan oṣù lọ (fún ẹni tí inú rẹ̀ bá máa ń fúnpọ̀ nígbà nǹkan oṣù), ẹ̀jẹ̀ tí ó máa ń yọ náà sì máa ń pọ̀ ju ti nǹkan oṣù lọ. Ẹ̀jẹ̀ dídì tí ó tóbi tó ọsàn náà lè jáde lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ tí o bá lo misoprostol. Fún àwọn obìnrin kan, ìrora inú fífúnpọ̀ yìí kò ní ga jara lọ, ẹ̀jẹ̀ náà ò sì ní ju ti nǹkan oṣù lọ.
Kàn sí elétò ààbò tí ẹ̀jẹ̀ ò bá jáde rárá tàbí kò pọ́, tí ìrora púpọ̀ (pàápàá ní èjìká ọ̀tún) tí apá ibuprofen ò ká bá tẹ̀lé e. Eléyìí lè jẹ́ àpẹẹrẹ oyún tí kò sí nínú ilé ọmọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò wọ́pọ̀, ó léwu gan-an. O lè kàn sí àwọn ọ̀rẹ́ wa ní www.safe2choose.org láti bá akọ́ṣẹ́mọṣẹ olùgbaninímọ̀ràn nípa oyún ṣíṣẹ́ tí o bá rò pé oyún náà ò tíì wálẹ̀.
Béèrè fún ìtọ́jú tí ẹ̀jẹ̀ bá kún páàdì méjì fọ́nfọ́n láàrin wákàtí kan fún wákàtí méjì léraléra lẹ́yìn tí o lérò pé oyún náà ti wálẹ̀. Kíkún páàdì náà túmọ̀ sí pé ẹ̀jẹ̀ kún un láti iwájú dé ẹ̀yìn, ẹ̀gbẹ́ sí ẹ̀gbẹ́, àti wọnú.
Lo ibuprofen mẹ́ta sí mẹ́rin (ọ̀kọ̀ọ̀kan 200mg) ní wákàtí mẹ́fà mẹ́fà tàbí mẹ́jọ mẹ́jọ sí ara wọn láti dín ìnira kù. O sì lè lo ibuprofen kí o tó lo misoprostol.
Lẹ́yìn tí misoprostol bá túká tán, o lè jẹun bí ó ṣe wù ọ́. Àwọn oúnjẹ tí kò oómi (bíi bisikíítì gbígbẹ àti tósìtì) máa ń dín inú rírun kù. Ẹ̀fọ́, ẹyin, ẹran (àwọn ẹran tí ó máa ń pupa tí a bá ṣe é tán) máa ń dá àwọn ohun tí ó ti bá ẹ̀jẹ̀ lọ padà sínú ara.
Lẹ́yìn tí misoprostol bá túká, o lè mu nǹkan olómi tí ó bá wù ọ́ (yàtọ̀ sí ọtí).
Yẹra fún orí mímú ní àkókò yìí kí òògùn náà ba à lè ṣiṣẹ́ bí ó ṣe yẹ. Ọtí mímú lè mú kí ẹ̀jẹ̀ máa dà síi, ó sì tún lè ṣe ìdíwọ fún iṣẹ́ àwọn òògùn tí ó máa ń dín ìrora kù àti àwọn tí ó ń dènà àkóràn (fún àwọn tí ó ní ìṣòro kan tàbí ìkejì). Ní àkótán, a gbà ọ ní ìyànjú kí o yẹra fún ọtí títí yóò fi dá ọ lójú pé oyún náà ti wálẹ̀ tí o sì wà ní àlàáfíà.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni oyún máa ń wálẹ̀ láàrín wákàtí mẹ́rin sí márùn-ún tí ara yóò sì bọ́ sípò láàrin wákàtí mẹ́rìnlélógún. Kò sì sí aburú nínú kí ẹ̀jẹ̀ díẹ̀ díẹ̀ máa yọ tàbí kán títí o ó fi rí nǹkan oṣù rẹ lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mẹ́ta sí mẹ́rin.
Ó lè rẹ èèyàn tàbí kí ó ní inú rírú, òtútù àti arábìnrin gbígbóná ní àkókò yìí. Ọpọlọpọ obìnrin ni ó sì sọ pé bí àwọn ṣe mọ̀ pé oyún náà ti wálẹ̀ ni pé ẹ̀jẹ̀ ń dá, ara wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí ní balẹ̀.
Ó ṣeéṣe kí ó jẹ́ iṣẹ́ abẹ ni wọ́n yóò fi gbé oyún lára obìnrin míì tí ó bá lo òògùn ìṣẹ́yún tí kò bá ṣiṣẹ́. Má ṣe gbàgbé pé ìtọ́jú wà fún irú oyún tí kò bá wálẹ̀ bẹ́ẹ̀ káàkiri àgbáyé. Ìwọ náà ní ẹ̀tọ́ sí ìtọ́jú yìí, kódà kí òfin má fi ààyè gba oyún ṣíṣẹ́ ní orílẹ̀ èdè rẹ.

Iṣẹyun Iṣẹgun ati Irọyin Ọla
lO è lóyún lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́jọ tí o bá ṣẹ oyún. Tí o bá máa ní àjọṣepọ̀, o lè lo nǹkan ìdènà oyún kí o má ba à ní oyún àìròtẹ́lẹ̀.
Rárá o, òògùn ìṣẹ́yún ò lè fà àbùkù sí ara ọmọ tí o bá lóyún rẹ lẹ́yìn tí o lò ó lára.
Rárá o, oyún ṣíṣẹ́ pẹ̀lú òògùn ò ní fa ìdíwọ́ fún oyún níní ní ọjọ́ iwájú.

Awọn ibeere FA Iṣẹyun miiran
A ò gbọ́dọ̀ gbé àwọn ọ̀nà tí a lè gbà ṣẹ́yún fún ìlànà ìdènà oyún (ara èyí tí ìdènà oyún pàjáwìrì wà). Àwọn ọ̀nà ìdènà oyún máa ń dí ọ̀nà ẹyin tàbí ṣe ìdíwọ́ fún ìpàdé àtọ̀ àti ẹyin. A ò lè fi àwọn ọ̀nà ìdènà oyún, tí ọkàn lára wọn jẹ́ ìdènà oyún pàjáwìrì ṣẹ́ oyún tí ó ti dúró. Lọ sí www.findmymethod.org láti kọ́ síi nípa àwọn ìlànà ìdènà oyún.
Òògùn idea oyún pàjáwìrì jẹ́ òògùn tí ó múnádóko tí kò sì béwu dé tí a fi ń dènà oyún nígbà tí a bá ní àjọṣepọ̀ láìlo ààbò. Wọ́n máa ń dá iṣẹ́ ẹ̀yà ara ti o máa ń pọ ẹyin dúró tàbí ṣe ìdíwọ́ fún ìpàdé ẹyin àti àtọ̀. Òògùn ìdènà oyún pàjáwìrì ò ní ba oyún tí ó ti dúró jẹ́. Wọ́n sì yàtọ̀ sí àwọn ìlànà oyún ṣíṣẹ́ (tí mifepristone àti misoprostol wà lára rẹ̀). Àwọn ìtọ́jú méjèèjì ṣe pàtàkì sí ìlera ìbí àti ìbálòpọ̀ káàkiri àgbáyé.
Oríṣi ìlànà oyún ṣíṣẹ́ méjì ni ó wà:
1) Oyún ṣíṣẹ́ ní ìlànà ìṣègùn òyìnbó: Nínú ìlànà yìí, a máa ń fi òògùn ṣé oyún. Wọ́n tún máa ń pè é ní “oyún ṣíṣẹ́ láìsí iṣẹ́ abẹ” tàbí “oyún ṣíṣẹ́ pẹ̀lú òògùn.
2) Oyún ṣíṣẹ́ pẹ̀lú iṣẹ́ abẹ: Nínú ìlànà yìí, akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ tí ó dáńtọ́ ni yóò gba ẹnu ọ̀nà ilé ọmọ láti yọ oyún náà nínú ilé ọmọ. Lára àwọn ohun tí wọn máa ń ṣe nínú ìlànà yìí ni, fífà oyún síta (manual vacuum aspiration) àti fífẹ ẹnu ọ̀nà ilé ọmọ láti yọ ohun tí ó wà níbẹ̀ (Dilatation and evacuation).
Fún àlàyé síwájú síi, o lè kàn sí wa ni info@howtouseabortionpill.org.