Àkíyèsí:Tí o bá ṣe àyẹ̀wò lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì tí o ṣẹ́yún, àyẹ̀wò yóò sì fi hàn pé o lóyún nítorí àwọn hòmóònù tí ó ṣì wà lára rẹ. Tí àwọn àmì pé o lóyún (àárẹ̀ ara, ọyàn rírọ̀, inú rírú àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ) bá sì ń yọ ọ́ lẹ́nu lẹ́yìn tí o lo òògùn ìṣẹ́yún, lọ rí dókítà.
Tí oyún bá ń wálẹ̀, àwọn àpẹẹrẹ òkè yìí kò mú ewu lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n má ṣe sàsùn para. Nǹkan lè ti fẹ́ yíwọ́ tí ó ba rí àwọn àpẹẹrẹ ìsàlẹ̀ wọ̀nyí:
Ẹ̀jẹ̀ tí ó ń dà yàà:Tí ẹ̀jẹ̀ bá kún páàdì méjì láàrin wákàtí kan lẹ́yìn tí o lérò pé oyún náà ti wálẹ̀, o ní láti rí elétò ìlera ní kíákíá nítorí ẹ̀jẹ̀ náà ti pọ̀jù. Kí ẹ̀jẹ̀ kún páàdì túmọ̀ sí pé páàdì náà kún fún ẹ̀jẹ̀ láti iwájú dé ẹ̀yìn, ẹ̀gbẹ́ sí ẹ̀gbẹ́, àti dénú.
Ìrora púpọ̀:Tí ìrora náà bá pọ̀ tí òògùn ibuprofen ò sì kápá rẹ, béèrè fún ìtọ́jú. Irú ìrora báyìí lè wáyé tí nǹkan bá ṣe oyún náà. A gbà aláboyún tí ó bá ń jẹ ìrora tí apá ibuprofen ò ká láti rí elétò ìlera nítorí ó léwu.
Àárẹ̀ ara líle:Ara rẹ lè máa gbóná, kí inú rẹ máa ru tàbí kí o máa bì ní ọjọ́ tí o bá lo misoprostol. Lẹ́yìn èyí, ó yẹ kí ara r̀ máa yá síi ni. Ṣùgbọ́n tí ó bá ń rẹ ọ síi, yára lọ rí dókítà.
Àwọn ìtọ́ka
This website may require anonymous cookies and various third party services to function properly. You can read our Terms & Conditions and Privacy Policies. By continuing to use this site you are giving us your consent to do this.