
Bi o ti N ṣiṣẹ
Àwọn èròjà tí wọn fi pèèlo òògùn ìsẹ́yún máa ń mú kí ó máa sì, kí ó sì máa ti ẹnu ilé ọmọ, èyí tí yóò mú kí ilé ọmọ súnkì tí yóò sì ti oyún náà síta.
Lẹ́yìn wákàtí kan sí méjì tí o bá lo ìwọ̀n òògùn misoprostol àkọ́kọ́, inú rẹ yóò bẹ̀rẹ̀ sí í máa fún pọ̀, ẹ̀jẹ̀ yóò sì máa jáde. Oyún máa ń sáábà wálẹ̀ láàrin wákàtí mẹ́rìnlélógun tí o bá lọ ìwọ̀n òògùn misoprostol tó kẹ́yìn. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni kò kí ń tó bẹ́ẹ̀.
Ti O ba jẹ Ifiyesi
Ó lè rí oyún náà bí ó bá wálẹ̀, tí o bá fẹ́. Ó lè dà bí èso àjàrà tí ó dúdú díẹ̀ tàbí awọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ kan; ó sì lè dà bíi àpò kékeré tí nǹkan funfun bò. Bí oyún náà bá ṣe dàgbà tó ni yóò sọ bí àwọn nǹkan tí ó máa jáde yìí ṣe máa tó – ó lè kéré bíi èékánná tàbí kí ó tóbi tó àtàǹpàkò. Tí o bá rí àwọn nǹkan wọ̀nyí, ó túmọ̀ sí pé oyún náà ti wálẹ̀. Nígbà mìíràn àwọn awọ yìí lè bá ẹ̀jẹ̀ jáde tí yóò sì nira láti rí. Ní irú àsìkò báyìí, ó ní láti wá a dáadáa kí o ba à lè ríi.
Itọkasi:
- “Induced Abortion.” American College of Obstetrics and Gynecologists.
https://www.acog.org/Patients/FAQs/Induced-Abortion - “Care for Women Choosing Medication Abortion.” The Nurse Practitioner.
https://journals.lww.com/tnpj/Citation/2004/10000/Care_for_Women_Choosing_Medication_Abortion.9.aspx - “Safe abortion: technical and policy guidance for health systems.”The World Health Organization.
https://apps.who.int/iris/bitstream/handle/10665/70914/?sequence=1