Lílo òògùn náà

Òògùn méjì ni ó wà tí à ń lò fún ìséyún: mifeprisitóònù àti mísópròsìtóòlù. Oyún sísé pèlú òògùn ń sisé dáada tí a bá lo àwon òògùn méjèjì yìí papò Àmò, tí mifeprisitóònù kò bá sí, mísópròsìtóòlù nìkan náà lé sisé láti séyún lónà àìléwu.

Pinu bóyá o féràn láti kó nípa àwon ìlànà àti séyún ní ònà tí kò panilára nípa lílo mifeprisitóònù àti mísópròsìtóòlù papò tàbí nípa lílo mísópròsìtóòlù nìkan.

How to Use

Kí o tó bèrè, ka ìyànjú wa lórii Kí o tó lo àwon òògù n Ríi dájú:

Àwon Ílànà fún oyún sísé nípa lílo Mifeprisitóònù àti Mísópròsìtóòlù

Fún ìséyún nípa lílo mifeprisitóònù àti mísópròsìtóòlù, wàá nílò láti lo mifeprisitóònù eyòkan èyí tí ó jé 200mg àti mérin sí méjo mísópròsìtóòlù èyítí ó jé 200mcg. Wàá tún fé ní òògùn araríro lówó bíi Ibupurofíìní láti dékùn araríro. Òògùn asetaminofínì àti parasitamólù kìí sisé fún ìrora nígbàtí a bá séyún nítorínáà a kò gbà yín níyànjú láti lo àwon òògùn náà.

Báyì ni a se lè lo mifeprisitóònù àti mísópròsìtóòlù papò láti séyún:

Ìpele ìkìní:

Gbé mifeprisitóònù eyòkan èyí tí ó jé 200mg mì pèlú omi.

Ìpele ìkejì:

Dúró fún wákàtí mérìnlèlógún sí méjìdínláàdóta.

Ìpele ìkéta:

Fi mísópròsìtóòlù mérin (èyítí ó jé 200mcg) sí abé ahón re kí o sì fi wón sílè síbè fún ogbòn ìséjú bí wón se ń túká. Ìwo kò gbodò sòrò tàbí jeun fún ogbòn ìséjú yìí, nítorínáà ó dára kí o wà ní ibi tí ó dáké tí enikéni kò ní yo é lénu. Léyìn ogbòn ìséjú, mu omi díè kí o sì gbé òògùn èyítí ó kù mì. Èyí tún jé àsìkò tó dára láti lo òògùn araríro bíi ibupurofíìnì, nítoríwípé inú rírun náà yó bèrè láìpé.

Ó ye kí o bèrè sí ní sèjè láti ojú ara àti kí o ní inú rírun láàrin wákàtí méta léyìn tí o bá ti lo mísópròsìtóòlù mérin náà.

Ípele ìkérin:

Léyìn wákàtí mérìnlèlógún tí o ti lo òògùn mísópròsìtóòlù mérin náà, tí o kò bá rí èjè tàbí tí kò bá dá e lójú wípé oyún sísé náà ti yege, fi òògùn mísópròsìtóòlù mérin míràn sí abé ahón re. Fi wón sílè síbè fún ogbòn ìséjú bí wón se ń túká. Léyìn ogbòn ìséjú, mu omi díè kí o sì gbé òògùn èyítí ó kù mì.

Àwon àkíyèsí míràn fún síséyún pèlú Mifeprisitóònù àti Mísópròsìtóòlù:

Kó nípa ohun tí ó ye kí o retí léyìn tí o bá lo mifeprisitóònù àti mísópròsìtóòlù níbí.

Tí o bá ni inú rírun tó pò tóbéègé, ibupurofíìnì jé òògùn tí ó dára láti farada ìrora. O lè ra ibupurofíìnì èyítí ó ní agbára 200mg ní ilé ìtòògùn (láìní ìwé láti òdo dókítà) ní òpòlopò orílé èdè. Lo méta sí mérin (èyítí ó jé 200mg) ní gbogbo wákàtí méfà sí méjo. Tí o bá nílò ohun kan síi láti dín ìrora kù, o tún lè lo òògùn Tailenólù méjì (èyítí ó jé 325mg) ní gbogbo wákàtí méfà sí méjo.

Tí ohun kan bá rú e lójú nípa Ílànà ìséyún náà tí o sì fé ìrànlówó, o lè késí àwon òre wa ní orí èro ayélujára www.safe2choose.org, www.womenhelp.org tàbí www.womenonweb.org.

Tí o bá lo àwon òògùn ìséyún náà mifeprisitóònù àti mísópròsìtóòlù, kò pidandan kí o lo rí onímò ìlera fún àyèwò ìtèsíwájú. Àwon òògùn yìí múnádóko tóbéègé tí ìgbìmò ìlera àgbáyé tí à ń pè ní World Health Organization pàse wípé ohun tí ó lè mú kí o lo fún àyèwò ìtèsíwájú ni:

  • Ara re kò dá, tàbí tí ìrora re kò dínkù léyìn ojó méjì tàbí méta. Tí èyí bá selé, wa ìtójú ìlera lésèkesè.
  • O sí ń ní àwon ààmì wípé oyún wà lára re léyìn òsè méjì tí o ti lo òògùn ìséyún náà.
  • Èjè tí ó ń jáde láti ojú ara re pò gidigan kò dè dínkù léyìn òsè méjì.

Àwon ílànà fún oyún sísé pelu Misoprostóólù nìkan

Kí o tó bèrè, ka ìyànjú wa lórii Kí o tó lo àwon òògù n Ríi dájú:

Ti mifeprisitóònù kò bá wà ní agbègbè re, o lè lo misoprostóólù nìkan láti séyún.

Fún oyún sísé pèlú misoprostóólù nìkan, wàá nílò láti lo òògùn misoprostóólù méjìlá èyítí o jé 200mcg. Wàá tún fé ní òògùn araríro lówó bíi Ibupurofíìní láti dékùn araríro. Òògùn asetaminofínì àti parasitamólù kìí sisé fún ìrora nígbàtí a bá séyún nítorínáà a kò gbà yín níyànjú láti lo àwon òògùn náà.

Báyì ni a se lè lo mísópròsìtóòlù nìkan láti séyún:

Ìpele ìkìní:

Fi mísópròsìtóòlù mérin (èyítí ó jé 200mcg) sí abé ahón re kí o sì fi wón sílè síbè fún ogbòn ìséjú bí wón se ń túká. Ìwo kò gbodò sòrò tàbí jeun fún ogbòn ìséjú yìí, nítorínáà ó dára kí o wà ní ibi tí ó dáké tí enikéni kò ní yo é lénu. Léyìn ogbòn ìséjú, mu omi díè kí o sì gbé òògùn èyítí ó kù mì. Èyí tún jé àsìkò tó dára láti lo òògùn araríro bíi ibupurofíìnì, nítoríwípé inú rírun náà yó bèrè láìpé.

Ìpele ìkejì:

Dúró fún wákàtí méta.

Ìpele ìkéta:

Fi mísópròsìtóòlù (èyítí ó jé 200mcg) mérin sí abé ahón re kí o sì fi wón sílè síbè fún ogbòn ìséjú bí wón se ń túká

Ípele ìkérin:

Dúró fún wákàtí méta míràn.

Ìpele ìkárún:

Fi mísópròsìtóòlù mérin míràn sí abé ahón re kí o sì fi wón sílè síbè fún ogbòn ìséjú bí wón se ń túká.

Ó ye kí o bèrè sí ní sèjè láti ojú ara àti kí o ní inú rírun nígbàtí o bá ń lo òògùn náà. Ríi dájú wípé o lo gbogbo òògùn méjìlá náà bótilè jè wípé o bèrè síní rí èjè láti ojú ara re kí o to lo gbogbo òògùn náà tán.

Àwon àkíyèsí míràn fún síséyún pèlú Mísópròsìtóòlù:

Kó nípa ohun tí ó ye kí o retí léyìn tí o bá lo mísópròsìtóòlù níbí.

Tí o bá ni inú rírun tó pò tóbéègé, ibupurofíìnì jé òògùn tí ó dára láti farada ìrora. O lè ra ibupurofíìnì èyítí ó ní agbára 200mg ní ilé ìtòògùn (láìní ìwé láti òdo dókítà) ní òpòlopò orílé èdè. Lo méta sí mérin (èyítí ó jé 200mg) ní gbogbo wákàtí méfà sí méjo. Tí o bá nílò ohun kan síi láti dín ìrora kù, o tún lè lo òògùn Tailenólù méjì (èyítí ó jé 325mg) ní gbogbo wákàtí méfà sí méjo.

Tí ohun kan bá rú e lójú nípa Ílànà ìséyún náà tí o sì fé ìrànlówó, o lè késí àwon òre wa ní orí èro ayélujára www.safe2choose.org, www.womenhelp.org tàbí www.womenonweb.org.

Tí o bá lo mísópròsìtóòlù, kò pidandan kí o lo rí onímò ìlera fún àyèwò ìtèsíwájú. Àwon òògùn yìí múnádóko tóbéègé tí ìgbìmò ìlera àgbáyé tí à ń pè ní World Health Organization pàse wípé ohun tí ó lè mú kí o lo fún àyèwò ìtèsíwájú ni:

  • Ara re kò dá, tàbí tí ìrora re kò dínkù léyìn ojó méjì tàbí méta. Tí èyí bá selé, wa ìtójú ìlera lésèkesè.
  • O sí ń ní àwon ààmì wípé oyún wà lára re léyìn òsè méjì tí o ti lo òògùn ìséyún náà.
  • Èjè tí ó ń jáde láti ojú ara re pò gidigan kò dè dínkù léyìn òsè méjì.

Àwọn òǹkọ̀wé:

Itọkasi: