Bí Òògùn Ìsẹ́yún Ní Ìlànà Ìlera Ṣe Ń Ṣíṣẹ́
Àwọn èròjà tí wọn fi pèèlo òògùn ìsẹ́yún ní ìlànà ìlera máa ń ṣíṣẹ́ nípa mímú kí inú ojú ora là (tí ó sì ń sí ilé ọmọ) tí ò sì ń fún ilé ọmọ pọ kí oyún náà le jáde.
Pẹ̀lú òògùn ìsẹ́yún ní ìlànà ìlera misoprostol, lẹ́yìn wákàtí kan sí méjì tí o bá lòó inú rẹ yóò bẹ̀rẹ̀ sí í máa fún pọ̀, ẹ̀jẹ̀ yóò sì máa jáde. Oyún náà má ń sáábà wálẹ̀ láàrin wákàtí mẹ́rìnlélógun tí o bá lọ òògùn misoprostol tó kẹ́yìn. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni kò kí ń tó bẹ́ẹ̀.
Ti O ba jẹ Ifiyesi
Àwọn wọ̀nyí ní àpẹẹrẹ láti mọ wípé oyún náà ti ṣẹ́ lèyín tó bá lo òògùn ìsẹ́yún:
- Ó lè rí oyún náà bí ó bá wálẹ̀, tí o bá fẹ́. Ó lè dà bí èso àjàrà tí ó dúdú díẹ̀ tàbí awọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́
- ó sì lè dà bíi àpò kékeré tí nǹkan funfun sì yíì ká.
Bí oyún náà bá ṣe dàgbà sí ni yóò sọ bí àwọn nǹkan tí ó máa jáde yìí ṣe máa pọ̀ tó – ó lè kéré bíi èékánná tàbí kí ó tóbi tó àtàǹpàkò.
Tí o bá rí àwọn nǹkan wọ̀nyí, ó túmọ̀ sí pé oyún náà ti wálẹ̀. Nígbà mìíràn àwọn awọ yìí lè bá ẹ̀jẹ̀ jáde tí yóò sì nira láti rí. Ní irú àsìkò báyìí, ó ní láti wá a dáadáa kí o ba à lè ríi. Tí ò bá ń yàgbẹ́ gburu nítorí òògùn ìsẹ́yún yìí, ó le ṣòro láti mọ. Má dàmú ara rẹ tí ó bá ṣẹlẹ̀ àwọn ipa òògùn ni.
Itọkasi:
- “Induced Abortion.” American College of Obstetrics and Gynecologists.
https://www.acog.org/Patients/FAQs/Induced-Abortion - “Care for Women Choosing Medication Abortion.” The Nurse Practitioner.
https://journals.lww.com/tnpj/Citation/2004/10000/Care_for_Women_Choosing_Medication_Abortion.9.aspx - “Safe abortion: technical and policy guidance for health systems.”The World Health Organization.
https://apps.who.int/iris/bitstream/handle/10665/70914/?sequence=1