Ta ni ó lè lo òògùn oyún ṣíṣẹ́?

Mo sanra gan-an, ṣé iye òògùn kan náà ni mo máa lò?

Bẹ́ẹ̀ni, iye òògùn kan náà ni gbogbo ènìyàn máa lo. Ìwádìí fi hàn pé iṣẹ́ òògùn náà ò kan bí èèyàn bá ṣe tóbi tó. O ò nílò òògùn púpọ̀ tàbí ìlànà mìíràn.

Tí mo bá ní oyún ìbejì ńkọ́?

Ìlànà kan náà ni ó wà fún oyún ìbejì, o ò ní láti lo òògùn púpọ̀.

Ṣe yóò sì ṣiṣẹ́ tí mo bá ti lò ó rí?

Bẹ́ẹ̀ni, oyún kọ̀ọ̀kan yàtọ̀ gédégbé sí ara wọn. Kódà kí o ti lò ó rí, nǹkan tí o lò ní àkọ́kọ́ náà ni ó máa lò fún oyún mìíràn tí o fẹ́ ṣẹ́.

Ǹjẹ́ mo lè lo misoprostol tí ẹ̀rọ ìdènà oyún bá wà ní inú mi?

Tí ẹ̀rọ ìdènà oyún (èyí tí wọ́n ká tàbí èyí tí ó ní hòmóònù "progesterone" nínú) bá wà nínú ilé ọmọ rẹ, o gbọ́dọ̀ yọ ọ́ kí o tó ṣẹ́yún náà.

Ṣe mo lè lo misoprostol tí mo bá ń fọ́mọ lọ́yàn?

Tí o bá ń fọ́mọ lọ́yàn, misoprostol lè fa ìgbẹ́ gbuuru fún ọmọ náà. Láti dènà èyí, dúró fún wákàtí mẹ́rin lẹ́yìn tí o bá lo òògùn tán kí o tó fọ́mọ lọ́yàn.

Ǹjẹ́ mo lè lo òògùn ìṣẹ́yún tí mo bá ní HIV?

Tí o bá ní HIV, ríi dájú pé àárẹ̀ ò mú ọ, o sì ń lo òògùn tí ó ń gbógun ti kòkòrò àìfojúrí HIV (antiretroviral).

Ṣé mo lè lo òògùn oyún ṣíṣẹ́ tí mo bá ní anémíà?

Tí o bá ní anémíà (àìtó áyọ́ọ̀nù nínú ẹ̀jẹ̀), wá elétò ìlera tí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ò jìnà ju ọgbọ̀n ìṣẹ́jú sí ọ̀dọ̀ rẹ lọ tí ó sì lè ṣe ìtọ́jú rẹ tí o bá nílò rẹ̀. Tí anémíà rẹ bá lè, gba àṣẹ dókítà kí o tó lo òògùn ìṣẹ́yún.

Ṣe òògùn ìṣẹ́yún ò ní pa mí lára tí mo bá ti bímọ pẹ̀lú iṣẹ́ abẹ rí?

Rárá, kò sí ewu tí ò bá ti ṣẹ́ oyún náà láìpẹ́ tí o ní i kódà kí o ti bímọ pẹ̀lú iṣẹ́ abẹ rí.

Tí mo bá lo òògùn ìṣẹ́yún ṣùgbọ́n tí oyún náà ò wálẹ̀, ṣe ọmọ tí mo bá bí ò ní ní àbùkù lára?

Kò tíì sí àsopọ̀ láàrín mifepristone àti àbùkù ara ọmọ ṣùgbọ́n misoprostol lè mú u ṣẹlẹ̀. Tí o bá lo misoprostol tí oyún náà sì wà lára rẹ, ó ṣeéṣe kí oyún náà wálẹ̀ fúnraàrẹ. Tí oyún náà ò bá sì wálẹ̀ títí àkókò ìbí fi tó, ewu kí ọmọ náà ní àbùkù lára jẹ́ idà kan nínú ọgọ́rùn-ún (1%)

Mo ṣe iṣẹ́ abẹ ìsọnidi aláìlèbímọ. Kò ṣiṣẹ́, mo sì lóyún. Inú ọ̀nà tí ẹyin máa ń gbà dé ilé ọmọ ni oyún náà wà. Mo tún ti wá lóyún. Ṣé kò ní pa mí lára tí mo bá ṣẹ́yún?

Rárá o, ó léwu láti lo òògùn ìṣẹ́yún nígbà tí ó ṣeéṣe kí oyún náà má wà nínú ilé ọmọ. Nítorí pé o ti ṣe iṣẹ́ abẹ ìsọnidi àláìlèbímọ, apá wà nínú ọ̀nà tí ẹyin ń gbà dé ilé ọmọ, ó súnmọ́ kí ó jẹ pe oun ni ìdí tí oyún tí o ní kẹ́yìn ṣe bọ́ sí inú rẹ̀. Inú ọ̀nà yìí ni àtọ̀ ti máa ń sọmọ. Tí oyún bá ti ń dàgbà, yóò máa lọ sí ilé ọmọ ṣùgbọ́n nítorí pé apá ti wà ní ọ̀nà náà, kò lè ráyè kọjá. Oyún náà ó sì máa dàgbà sí ibi tí ó wà. Bí ó ṣe ń dàgbà síi, inú ọ̀nà tí o wà lè bẹ́, èyí tí ó lè fa kí ẹ̀jẹ̀ máa ya nínú rẹ, ní èyí tí ó léwu. Ó ṣeéṣe kí oyún eléyìí náà má sí nínú ilé ọmọ. Má ṣe dá òògùn oyún ṣíṣẹ́ lò fúnraàrẹ àyàfi tí elétò ààbò bá rí àrídájú pé inú ilé ọmọ ni oyún náà wà.

Báwo ni mo ṣe lè ṣẹ́yún tí wọ́n bá ní inú ilé ọ̀nà tí ẹyin ń gba de inú ilé ọmọ ni oyún mi wá?

Àkọ́kọ́ náà, ó gbọ́dọ̀ mọ̀ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìnrin ò ní mọ̀ pé àwọn ní irú oyún báyìí àfi tí wọ́n bá ya àwòrán inú. Oyún inú ọ̀nà yìí léwu débi pé àwọn orílẹ̀-èdè tí òfin ò ti fààyè gba oyún ṣíṣẹ́ gan-an fi ọwọ́ sí kí wọn ṣẹ oyún yìí.

Bẹ́ẹ̀ni, iye òògùn kan náà ni gbogbo ènìyàn máa lo. Ìwádìí fi hàn pé iṣẹ́ òògùn náà ò kan bí èèyàn bá ṣe tóbi tó. O ò nílò òògùn púpọ̀ tàbí ìlànà mìíràn.

Ìlànà kan náà ni ó wà fún oyún ìbejì, o ò ní láti lo òògùn púpọ̀.

Bẹ́ẹ̀ni, oyún kọ̀ọ̀kan yàtọ̀ gédégbé sí ara wọn. Kódà kí o ti lò ó rí, nǹkan tí o lò ní àkọ́kọ́ náà ni ó máa lò fún oyún mìíràn tí o fẹ́ ṣẹ́.

Tí ẹ̀rọ ìdènà oyún (èyí tí wọ́n ká tàbí èyí tí ó ní hòmóònù "progesterone" nínú) bá wà nínú ilé ọmọ rẹ, o gbọ́dọ̀ yọ ọ́ kí o tó ṣẹ́yún náà.

Tí o bá ń fọ́mọ lọ́yàn, misoprostol lè fa ìgbẹ́ gbuuru fún ọmọ náà. Láti dènà èyí, dúró fún wákàtí mẹ́rin lẹ́yìn tí o bá lo òògùn tán kí o tó fọ́mọ lọ́yàn.

Tí o bá ní HIV, ríi dájú pé àárẹ̀ ò mú ọ, o sì ń lo òògùn tí ó ń gbógun ti kòkòrò àìfojúrí HIV (antiretroviral).

Tí o bá ní anémíà (àìtó áyọ́ọ̀nù nínú ẹ̀jẹ̀), wá elétò ìlera tí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ò jìnà ju ọgbọ̀n ìṣẹ́jú sí ọ̀dọ̀ rẹ lọ tí ó sì lè ṣe ìtọ́jú rẹ tí o bá nílò rẹ̀. Tí anémíà rẹ bá lè, gba àṣẹ dókítà kí o tó lo òògùn ìṣẹ́yún.

Rárá, kò sí ewu tí ò bá ti ṣẹ́ oyún náà láìpẹ́ tí o ní i kódà kí o ti bímọ pẹ̀lú iṣẹ́ abẹ rí.

Kò tíì sí àsopọ̀ láàrín mifepristone àti àbùkù ara ọmọ ṣùgbọ́n misoprostol lè mú u ṣẹlẹ̀. Tí o bá lo misoprostol tí oyún náà sì wà lára rẹ, ó ṣeéṣe kí oyún náà wálẹ̀ fúnraàrẹ. Tí oyún náà ò bá sì wálẹ̀ títí àkókò ìbí fi tó, ewu kí ọmọ náà ní àbùkù lára jẹ́ idà kan nínú ọgọ́rùn-ún (1%)

Rárá o, ó léwu láti lo òògùn ìṣẹ́yún nígbà tí ó ṣeéṣe kí oyún náà má wà nínú ilé ọmọ. Nítorí pé o ti ṣe iṣẹ́ abẹ ìsọnidi àláìlèbímọ, apá wà nínú ọ̀nà tí ẹyin ń gbà dé ilé ọmọ, ó súnmọ́ kí ó jẹ pe oun ni ìdí tí oyún tí o ní kẹ́yìn ṣe bọ́ sí inú rẹ̀. Inú ọ̀nà yìí ni àtọ̀ ti máa ń sọmọ. Tí oyún bá ti ń dàgbà, yóò máa lọ sí ilé ọmọ ṣùgbọ́n nítorí pé apá ti wà ní ọ̀nà náà, kò lè ráyè kọjá. Oyún náà ó sì máa dàgbà sí ibi tí ó wà. Bí ó ṣe ń dàgbà síi, inú ọ̀nà tí o wà lè bẹ́, èyí tí ó lè fa kí ẹ̀jẹ̀ máa ya nínú rẹ, ní èyí tí ó léwu. Ó ṣeéṣe kí oyún eléyìí náà má sí nínú ilé ọmọ. Má ṣe dá òògùn oyún ṣíṣẹ́ lò fúnraàrẹ àyàfi tí elétò ààbò bá rí àrídájú pé inú ilé ọmọ ni oyún náà wà.

Àkọ́kọ́ náà, ó gbọ́dọ̀ mọ̀ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìnrin ò ní mọ̀ pé àwọn ní irú oyún báyìí àfi tí wọ́n bá ya àwòrán inú. Oyún inú ọ̀nà yìí léwu débi pé àwọn orílẹ̀-èdè tí òfin ò ti fààyè gba oyún ṣíṣẹ́ gan-an fi ọwọ́ sí kí wọn ṣẹ oyún yìí.

Itọkasi

Oju opo wẹẹbu yii le nilo awọn kuki alailorukọ ati ọpọlọpọ awọn iṣẹ ẹnikẹta lati ṣiṣẹ daradara. O le ka Awọn ofin & Awọn ipo wa ati Awọn ilana Ìpamọ . Nipa tẹsiwaju lati lo aaye yii o fun wa ni igbanilaaye rẹ lati ṣe eyi.